Genevieve Nnaji jẹ́ òṣeré filmu ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà. Ní 2005 ó gba Ẹ̀bùn Akadẹ́mì Filmu ilẹ̀ Áfríkà gẹ́gẹ́ bíi Òṣeré Obìnrin Dídárajùlọ. Ìlú Èkó ni Genevieve Nnaji ti dàgbà. Ìkẹrin nínú àwọn ọmọ méjọ, ọ̀mọ̀wé ni àwọn òbí rẹ̀. Bàbá rẹ̀ siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ iṣẹ́-ẹ̀rọ (engineer) nígbàtí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ olùkọ́. Ò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Methodist Girls College ní Yaba, lẹ́yìn rẹ̀ ó tẹrísí Yunifásítì ìlú Èkó. Níbẹ̀ lówà tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ díèdíẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi òṣèré ni Nollywood. Nnaji bẹ̀rẹ̀ ìṣèré rẹ̀ láti ọmọdé ninu eré tẹlifísọ̀n Ripples nígbà tójẹ́ ọmọ ọdún 8. Ó tún ṣe ìpolówó ọjà bíi méèló kan nínú èyí tó jẹ́ fún Pronto àti ọṣẹ ìfọsọ OMO. Ní 2004 ó di aṣojú fún ọsẹ ìwẹ̀ Lux ìbáṣe ìgbọ̀wọ́ tọ́ fa èrè ínlá wá fun. Ni 1998 nígbà tójẹ́ ọmọ ọdún 19 wọn ṣe àmúhàn rẹ̀ sí àwọn olólùfẹ́ filmu ni Naijiria pẹ̀lú filmu tó ún jẹ́ Most Wanted. Lẹ́yìn rẹ̀ ó tún ṣe àwọn filmu bíi Last Party, Mark of the Beast àti Ijele. Ó ti kópa nínúu filmu tó tó 80 ni Nollywood. Nnaji ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn fún iṣẹ́ rẹ̀ ìkan nínú wọn jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi òṣèré obìnrin tódárajùlọ fún 2001 ní City People Awards, ó sì tún gba ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bíi Òṣèré Obìnrin tó dára jùlọ ní 2005 nínú àwọn Ẹ̀bùn Akadẹ́mì Filmu ilẹ̀ Áfríkà.
(ìtẹ̀síwájú...)