Ojúewé Àkọ́kọ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Nelson Mandela

Nelson Rolihlahla Mandela (ọjọ́ìbí 18 Oṣù Keje 1918) jẹ́ Ààrẹ Gúúsù Áfríkà lati 1994 di 1999, beesini ohun ni Aare Guusu Afrika akoko to je didiboyan ninu idiboyan toseluarailu eto idibo gbogbo eniyan. Kí ó tó di ààrẹ, Mandela je alakitiyan olodi eto apartaidi, ati olori Umkhonto we Sizwe, to je apa ologun Kongresi Omoorile-ede ara Afrika (ANC). Ni 1962 o je fifofinmu, o si je didalebi iwa ote ati awon esun miran. Nitorie won so si ewon fun igba lailai. Mandela lo odun 27 ni ewon, o lo opo odun yi ni Erekusu Robben. Leyin ijowo re kuro logba ewon ni ojo 11 Osu Keji 1990, Mandela lewaju egbe oloselu re ninu awon iforojomitorooro to fa oseluarailu gbogbo eya waye ni 1994. Gege bi aare lati 1994 de 1999, o sise fun ifowosowopo. Ni Guusu Afrika, Mandela tun je mimo bi Madiba, oye ti awon alagba idile Mandela unlo. Mandela ti gba ebun topo ju 250 lo laarin ogoji odun, ninu won ni Ebun Nobel Alafia 1993.

Nelson Mandela je ara eka kekere iran oba Thembu, to joba ni awon agbegbe Transkei ni Igberiko Cape ti Guusu Afrika. O je bibi ni Mvezo, abule kekere kan to budo si agbegbe Umtata, to je oluilu Transkei. Baba unla-unla baba re Ngubengcuka (to ku ni 1832), joba gege bi Inkosi Enkhulu, tabi ọba awon Thembu. Ikan ninu awon omokunrin oba ohun to nje Mandela, ni baba unla re ati ibi ti oruko idile re ti wa. Sibesibe nitoripe o je omo Inkosi latodo iyawo iran Ixhiba (eyun "idile olowo osi", awon omoomo eka ebi oba re ko le gori ite ni Thembu. Baba Mandela, Gadla Henry Mphakanyiswa, je oloye ni ilu Mvezo. Sugbon nitori aigboran si ijoba alamusin lenu, won yo Mphakanyiswa kuro ni ipo oye re won si ko ebi re lo si Qunu. Sibesibe, Mphakanyiswa ko kose lati je omo egbe Igbimo Onimoran Inkosi, beesini o kopa gidi lat ri pe Jongintaba Dalindyebo gun ori ite Thembu. Lojowaju Dalindyebo san ore yi pada nipa gbigba Mandela sodo bi omo nigbati Mphakanyiswa ku. Baba Mandela fe iyawo merin, pelu won o bi omo metala (okunrin merin ati obinrin mesan). Oruko abiso re Rolihlahla tumosi "fa eka igi", tabi "onijangbon". Rolihlahla Mandela lo je omo akoko ninu ebi re to lo si ile-eko nibi ti oluko re Miss Mdingane ti fun ni oruko Geesi "Nelson". (ìtẹ̀síwájú...)

W.E.B. DuBois

Ọjọ́ 23 Oṣù Kejì:

Àwọn ọlọ́jọ́ìbí lóòní...

Àwọn aláìsí lóòní...

Ọjọ́ míràn: 2425262728 | ìyókù...


Fàdákàolómi



Ẹ tún wo ÌròyìnWiki ní èdè Gẹ̀ẹ́sì
Boletus impolitus 2010 G2.jpg

Irú olú Boletus impolitus

Wikimedia logo family complete.svg Àwọn Iṣẹ́-ọwọ́ Míràn
Wikimedia Foundation ni ó gba àlejò Wikipedia, egbe-alasepo ti ki se fun ere ti o tun se alejo opo awon ise-owo miran:
Wikiàyásọ Wikiàyásọ
Àkójọ àwọn àmúsọ
Wikiatúmọ̀èdè Wikiatúmọ̀èdè
Atúmọ̀èdè orísirísi èdè
Wikispecies Wikispecies
Àkójọ àwọn irú ẹ̀dá
Wikiìròyìn Wikinews
Ìròyìn ọ́fẹ̀
Wikisource Wikisource
Àwọn àkọsíìwé ọ̀fẹ́
Commons Wikimedia Commons
Àwòrán, ìró àti fídéò
Wikifásítì Wikifásítì
Èlò ìkọ́ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́
Wikiìwé Wikiìwé
Ìwéẹ̀kọ́ àti ìwéàwòṣe ọ̀fẹ́
Meta-Wiki Meta-Wiki
Ibi àkóso ìṣẹ́-ọwọ́ Wikimedia
Wikidata Wikidata
Ìbùdó ìmò ọ̀fẹ́


Àkọ́jọ kíkúnrẹ́rẹ́ · Ibiàkóso àwọn èdè Wikipedia · Ìdásílẹ̀ èdè Wikipedia tuntun